Hymn

 ENGLISH LYRICS


1. Fading away like the stars of the morning,
    Losing their light in the glorious sun—- 
    Thus would we pass from the earth and its toiling,
    Only remembered by what we have done.

    Only remembered, only remembered, 
    Only remembered by what we have done ; 
    Thus would we pass from the earth and its toiling, 
    Only remembered by what we have done.

2. Shall we be missed, though by others succeeded,  
    Reaping the fields we in springtime have sown ?
    Yes, but the sowers must pass from their labours,
    Ever remembered by what they have done.

3. Only the truth that in life we have spoken,
    Only the seed that on earth we have sown ; 
    These shall pass onward when we are forgotten, 
    Fruits of the harvest and what we have done.

4. Oh, when the Saviour shall make up His jewels,
    When the bright crowns of rejoicing are won, 
    Then shall His weary and faithful disciples 
    All be remembered by what they have done.
Amen.

YORUBA LYRICS

1.  A o kọja lọ bi àwọn 'rawọ òórọ̀
    T' ìmọ́lẹ̀ wọn n ran n'nu oorun ogo, 
    Bẹ́ẹ̀ l' a o lọ kúrò l' aye ati 'ṣẹ rẹ̀, 
    A o maa ranti wa nip' on t' a ti ṣe. 

    Wọn yoo ṣe 'ranti, wọn yoo ṣe 'ranti,
    A o maa ranti wa nip' on t' a ti ṣe, 
    Bẹ́ẹ̀ l' a o lọ kúrò l' aye ati 'ṣẹ rẹ̀, 
    A o maa ranti wa nip' on t' a ti ṣe. 

2. A o ha kuro k' àwọn miran rọ́pò wa,
    Lati maa kore oko t' a ti gbìn?, 
    Bẹ́ẹ̀ l' àwọn òṣìṣẹ́ yoo fi 'ṣẹ́ sílẹ̀, 
    A o maa ranti wa nip' on t' a ti ṣe. 

3. Kìkì òótọ́ ti a ba ti sọ láyé, 
    Pẹ̀lú 'rúgbìn t' a ti gbìn laye yii, 
    Yoo tẹ̀síwájú t' a ba ti gbàgbé wa, 
    Eso ikore at' on t' a ti ṣe. 

4. 'Gbà t' Olúwa yoo k' àwọn ayanfẹ Rẹ̀, 
    T'ao jere adé aláyọ̀ t' ó ntàn, 
    'Gba naa l' ao ranti àwọn olootọ Rẹ̀, 
    T' àárẹ̀ ti mu nip' on ti wọ́n ti ṣe.
Amin.

Composed by ‎Horatius Bonar